A TI YA WA SOTO NINU AYE
ESE BIBELI: Ise 26:18, Galatia 6:14, I Johannu 5:4-5, II Korinti 5:20, II Peteru 3:12
ESE BIBELI: Ise 26:18, Galatia 6:14, I Johannu 5:4-5, II Korinti 5:20, II Peteru 3:12
AKOSORI: "Lati la won ni oju, ki won ki o le yi pada kuro ninu okunkun si imole, ati kuro lowo agbara satani si Olorun, ki won ki o le gba idariji ese, ati ogun pelu awon ti a so di mimo nipa igbagbo ninu mi
(Ise 26:18)
(Ise 26:18)
IFAARA
Ogun ibi ti o se koko ni ki a ya ara wa soto ninu aye nipa fifi aye wa, ero okan wa jin fun Olorun patapata. Kristieni gbodo ni afojusun ti Orun ati ireti ipin rere.
ALAYE LORI EKO
A TI YA WA SOTO NINU AYE
- Awa ju asegun lo nipase Jesu Kristi (Roomu 8:37)
- A je asoju fun Kristi (II Korinti 5:20)
- A wa laaye nipase igbagbo wa ninu omo Olorun (Galatia 6:14)
- A ti di oku si nkan ti aye
- A ti ji wa dide pelu Kristi, a si jokoo ninu awon orun (Efesu 2:6)
- A ti di alajumo gbe pelu awon eniyan Olorun (ebi agbo ile Olorun), (Efesu 2:9)
- A ti fun wa ni ireti ogo (Kolose 1:27)
- A ti gba wa kuro ninu ijoba okunkun, a si ti mu wa wa sinu ijoba Olorun (Kolose 1:13)
- A n foju sona fun orun titun, aye titun ati ibugbe ododo (II Peteru 3:12)
- A ti segun aye (I Johannu 5:4-5)
IPARI
A ni ipin ologo nigba ti a ba wa ninu Jesu Kristi, a nilati bi iwa awawi aimo sonu ki a ko irufe eni ti a je ninu Kristi lati inu oro Olorun, ki a si maa gbe ninu imo otito. A nilati je ki aye ati eda wa atijo ku, ki aje olugboran si Olorun Baba, ki a ma gbe ninu agbara Olorun.
IBEERE
- Kini ogun ibi ti o se koko fun Kristieni?
- Kini a ni nigbati a ba wa ninu Jesu Kristi?
- Kini eredi iyasoto wa ninu aye?
- Kini a le se ki a to le ri ogun ibi wa gba?
- Nje a ti ya o soto ninu aye bi?
No comments:
Post a Comment