28 June 2017

ISORO ATI IDANWO

ISORO ATI IDANWO
 
ESE BIBELI - I Johannu 2:15-17, Owe 1:10, Jakobu 1:12-16, Heberu 4:15
AKOSORI - "Sugbon olukuluku n a dan wa, nigba ti a ba ti owo ifekufe ara re faa lo ti a si tan an je" Jakobu 1:14

IFAARA
Ni kete ti a ti bi wa ni a ti ni ominira lati ya kuro ninu sise ife Olorun. Bibeli so pe igbe aye wa ti atijo lo fa eyi (Roomu 7:25). Idi ti a fi n ya kuro ni oju ti oro Olorun ti la sile fun wa. Ti a ba di atunbi ati omo Olorun, ese le maa seju siwa pe ki a da oun, sugbon ki a sa fun dida ese. Ohun ti Olorun fe fun wa ni ki a se, ki a si ma pada si iwa aisedede wa atijo.

ALAYE LORI EKO 
1.  KINNI IDANWO
2. ONA TI IDANWO NGBA DE BA ENIYAN 

1.  KINNI IDANWO
"Orisirisi itumo ni a ti fun idanwo lati nkan bi egberun odun meji sehin. Itumo abara meji (iyen tibi-tire) ni won ti fun ri" iyen ni :didan nkan wo" tabi "ki emi esu mu eniyan se nkan". Itumo rere fun idanwo ni ki Olorun je won dan aye wa wo pelu erongba lati ni idagbasoke ti Emi.
Itumo ibi ti idanwo ni ona ero ti satani n lo lati tan wa lati tapa si ona ti Olorun ti la sile fun wa. (Arthur Wallia: Living Gods Way) (Gbigbe aye ni ilana ti Olorun)

2. ONA TI IDANWO NGBA DE BA ENIYAN
Olorun ko dan enikeni wo ri (Jakobu 1:13). Satani lo maa ndan wa wo nipase fifi oun bintin tan wa je (Jakobu 1:14) tabi ki o lo awon elese lati tan wa je (Owe 1:10). Ona META yii ni idanwo ti le waye.
1. Ifekufe ti ara
2. Ifekufe ti oju
3. Igberaga ti aye (I Johannu 2:15-17)
Lara awon ona ti satani n gba dan wa wo ni iwonyi:
1. Ki a maa se aigboran (Gen. 3:1-7)
2. Itanje ti ibalopo aito (Gen. 39:7-10)
3. Fifi ife eniyan tabi nkan saaju ife wa si Olorun (Malaki 4:9)
4. Aniju ife owo (Johannu 12:6)
5. Gbigba ogo Olorun fun ara wa (Ise 12:21-23)
6. Gbigba ofofo, oro kelekele tabi gboyii-sooyii laaye (I Korinti 10:10, Kolose 3:8-9)

Satani n dan wa wo lati pa wa run ni. O fe ki a maa dese, ki iyapa to gbooro le wa laarin awa ati Olorun. Eleyi yo si je ki a padanu awon nkan rere ti Olorun. Eru ese wa yio wa wa lorun to bee gee debi pe eru yo maa ba wa lati lo sodo Baba wa ti n be lorun. Lasiko yi ni satani yo raye wonu aye wa. A o maa fi aye wa sinu satani, a o maa ti igbekun satani kan bo sinu omiran. Gbogbo igbesi aye wa  ni yo si wa labe igbekun satani. Eleyi dabi igba ti satani n gun esin wa nikese, ti o si n dari wa sibi ti o ba wu u.

IPARI
"Nitori a ko ni olori alufa to kole sai ba ni ikedun ninu ailera wa, eni ti a ti danwo ni ona gbogbo gege bi awa, sugbon lailese" (Heb. 4:15). Bi a se n dan wa wo yii ni a ti dan Jesu wo ri, sugbon Jesu ko se, ko si je ki idanwo naa bori oun, o le gba awa Kristieni la, ki a le gbe aye wa gege bi oun naa ti gbe aye tire. Idanwo Olorun je si iye, nigbati idanwo satani je ti iku (Jakobu 1:12-16). Lakotan, awa gegebi omo ehin Jesu, a ko gbodo jaya nigbati isoro tabi idanwo ba koju wa, nitoripe Olorun yo mu wa bori.
IBEERE
1. Daruko ona meta ti idanwo ti le waye?
2. So die lara awon ona ti satani ngba dan wa wo?
3. Kini idanwo?
4. Salaye itumo rere fun idanwo ati itumo ibi ti idanwo?
5. Kini abayori idanwo ti Olorun ati idanwo ti satani?

No comments:

Post

Message From The Lord

Popular Post