AKORI: EREDI ISORO ATI IDANWO
ESE BIBELI: I Peteru 1:6-7, Jobu 1:12, Jobu 2:6, Jobu 42:1-17, Deuteronomy 8:2-5, I Korinti 10:13
AKOSORI: "Ninu eyi ti eyin n yo pupo, bi o tile se pe nisisiyi fun igba die, niwon bi oti ye, a ti fi opolopo idanwo ba yin ninu je: Ki idanwo igbagbo yin, ti o ni iye lori ju wura tii segbe lo, bi o tile se pe ina ni a fi n dan an wo, ki a le rii fun iyin, ati ola, ati ninu ogo ni igba ifarahan Jesu Kristi" I Peteru 1:6-7
IFAARA
"Eyin ara mi, nigba ti eyin ba bo sinu oniruuru idanwo, e ka gbogbo re si ayo, ki e si mo pe idanwo igbagbo yin n sise suuru" (Jakobu 1:2-3). Ninu Jobu 1:12 ati Jobu 2:6, a rii pe bi o tile je pe Olorun gba Satani laye lati dan Jobu eni tii se olooto ati alailese eniyan wo. Olorun paala si bi idanwo naa yoo se to. Ni igbehin, Jobu pelu iranlowo Olorun bori isoro ati idanwo re, O jinle ninu Emi, o si seso Emi fun Olorun. (Jobu 42: 1-17).
ALAAYE LORI EKO
IDI TI OLORUN FI N JE KI KRISTIENI NI ISORO ATI KI A DAN WON WO
- Won n fi aworan bi a se je han - Idanwo n fiwa han iru eda ti a le je ti anfani ba suyo lojiji.
- Won fi idi ona ti o maa gba se ipinu lojo iwaju mule. Pataki isoro ati idanwo ni lati se ipinu lori ohun ti a o se tabi duro lo lori. Ti a ba fi aye gba idanwo laaye lati bori wa, idanwo a je gaba lewa lori ni. Ona lati le ko ese sile laye wa yo maa gberu si ni. Sugbon ti idanwo ko ba raaye bori wa, a o maa dagba soke ninu emi, a o si le maa se ipinu to rinle ninu emi lojo iwaju.
- Won wa lati mu wa gbaradi lati gba awon nkan ti Olorun fe fun wa, Eyi wa lowo bi a ba lagbara lati gba ebun ti Olorun ti seleri naa. Irin le kan ti opo lilu ba ba a. Isoro ati idanwo lo le mu wa gbaradi lati gba ohun ti a n fe lowo Olorun. Bi idanwo ba ti n koju wa ni iranlowo Olorun yo maa fokan wa bale pe a o saseyori. Olorun ko le je ki a dan wa wo debi ohun ti emi wa ko le ko. Nitori pe ki a to dan wa wo, Olorun ti fowo sii. Sugbon a nilati ko ipa tiwa nipase gbigbe aye igboran si ase Olorun, ki a ma si fi ara wa si ipo ti ese yo ti maa seju si wa.
- Won fi ailera ara wa han, eyi ti yo mu wa bere fun agbara ati oore-ofe Olorun (2Kronika 32:31, Deut 8:2).
- Olorun mu ki won sele si wa lati je ki:
- a je oniwa pele, o je Olukoni fun wa, ki a si ko ara wa nijaanu (Deut 8:2-5)
- tun wa se (Orin Dafidi 66:10)
- a ye ipile wa wo (I Korinti 3:10-15)
- a yo ohun gbogbo ti o le mu ki a maa se sege-sege kuro (Heberu 12:25-29)
- a ni emi ifarada ti yo jee ki a dagba ninu emi ni opin eyi ti a ko ni se alaini ohunkohun (Jakobu 1:2-4)
- a fi idi igbagbo wa mule (I Peteru 1:6-7)
- ki a je olubori (Ifihan 2:3)
IPARI
Tarugbo-todo Kristeni ni o ye ki o mo nipa fifi ese danra wo. O je okan lara iriri awon omo Olorun. Sugbon sa o, Kristeni le ma dese, nitori pe Olorun ti fun won lagbara lati bori idanwo. "Ko si idanwo kankan ti o ti baa yin bikose iru eyi ti o mo niwon fun eniyan. Sugbon olododo ni Olorun, eni ti ki yoo je ki a dan an yin wo ju bi eyin ti le gba; sugbon ti yoo si se ona atiyo pelu ninu idanwo naa, ki eyin ki o ba a le gba a" (I Korinti 10:13)
IBEERE
- Kini eredi isoro ati idanwo wa?
- Kini idi ti Olorun fi gba satani laaye lati dan Jobu wo?
- Nje idanwo le bori omo Olorun tooto bi?
- Daruko awon idi ti Olorun fi n je ki Kristeni ni isoro ati ki a dan won wo?
- Kini ewu ti o wa ninu fifi ese danrawo?
No comments:
Post a Comment